Native Bible

Joshua 4:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

kí ó sì jẹ́ àmì láàrín yín. Ní ọjọ́ iwájú, nígbà tí àwọn ọmọ yín bá béèrè lọ́wọ́ yín pé, ‘Kí ni òkúta wọ̀nyí dúró fún?’

Joshua 4:6 in English

Joshua 4:6 · Berean Standard Bible

to serve as a sign among you. In the future, when your children ask, ‘What do these stones mean to you?’

Context

4Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua pe àwọn ọkùnrin méjìlá tí ó ti yàn nínú àwọn ọmọ Israẹli, ẹnìkan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, 5ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ kọjá lọ ní iwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa Ọlọ́run yín sí àárín odò Jordani. Kí olúkúlùkù yín gbé òkúta kọ̀ọ̀kan lé èjìká a rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí iye ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli, 6kí ó sì jẹ́ àmì láàrín yín. Ní ọjọ́ iwájú, nígbà tí àwọn ọmọ yín bá béèrè lọ́wọ́ yín pé, ‘Kí ni òkúta wọ̀nyí dúró fún?’ 7Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò dá wọn lóhùn pé, nítorí a gé omi odò Jordani kúrò ní iwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa. Nígbà tí a rékọjá a Jordani, a gé omi Jordani kúrò. Àwọn òkúta wọ̀nyí yóò sì jẹ́ ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli láéláé.” 8Báyìí ni àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe bí Joṣua ti pàṣẹ fún wọn. Wọ́n gbé òkúta méjìlá láti àárín odò Jordani gẹ́gẹ́ bí iye ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli, bí Olúwa ti sọ fún Joṣua; wọ́n sì rù wọ́n kọjá lọ sí ibùdó, ní ibi tí wọ́n ti gbé wọn kalẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.