Joṣua 3:8
Joshua 3:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Sọ fún àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí náà, ‘Nígbà tí ẹ bá dé etí omi Jordani, ẹ lọ kí ẹ sì dúró nínú odò náà.’ ”
Joshua 3:8 in English
Joshua 3:8 · Berean Standard Bible
Command the priests carrying the ark of the covenant: ‘When you reach the edge of the waters, stand in the Jordan.’”
Context
6Joṣua sọ fún àwọn àlùfáà pé, “Ẹ̀yin, ẹ gbé àpótí ẹ̀rí náà kí ẹ̀yin kí ó sì máa lọ ṣáájú àwọn ènìyàn.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé e sókè, wọ́n sì ń lọ ní iwájú u wọn. 7Olúwa sì sọ fún Joṣua pé, “Òní yìí ni Èmi yóò bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ọ ga ní ojú u gbogbo àwọn ará Israẹli, kí wọn lè mọ̀ pé Èmi wà pẹ̀lú rẹ gẹ́gẹ́ bí mo ṣe wà pẹ̀lú Mose. 8Sọ fún àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí náà, ‘Nígbà tí ẹ bá dé etí omi Jordani, ẹ lọ kí ẹ sì dúró nínú odò náà.’ ” 9Joṣua sì sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹ súnmọ́ ibí kí ẹ̀yin kí ó sì fetí sí ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run yín. 10Èyí ni ẹ̀yin yóò fi mọ̀ pé Ọlọ́run alààyè wà ní àárín yín àti pé dájúdájú yóò lé àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti, Hifi, Peresi, Girgaṣi, Amori àti Jebusi jáde níwájú u yín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.