Native Bible

Joshua 3:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Odò Jordani sì máa ń wà ní kíkún ní gbogbo ìgbà ìkórè. Ṣùgbọ́n bí àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí ti dé odò Jordani tí ẹsẹ̀ wọn sì kan etí omi,

Joshua 3:15 in English

Joshua 3:15 · Berean Standard Bible

Now the Jordan overflows its banks throughout the harvest season. But as soon as the priests carrying the ark reached the Jordan and their feet touched the water’s edge,

Context

13Bí àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí Olúwa, Olúwa gbogbo ayé bá ti ẹsẹ̀ bọ odò Jordani, omi tí ń ti òkè sàn wá yóò gé kúrò yóò sì gbá jọ bí òkìtì kan.” 14Nígbà tí àwọn ènìyàn gbéra láti ibùdó láti kọjá nínú odò Jordani, àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí náà ń lọ níwájú wọn. 15Odò Jordani sì máa ń wà ní kíkún ní gbogbo ìgbà ìkórè. Ṣùgbọ́n bí àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí ti dé odò Jordani tí ẹsẹ̀ wọn sì kan etí omi, 16omi tí ń ti òkè sàn wá dúró. Ó sì gbá jọ bí òkìtì ní òkèèrè, ní ìlú tí a ń pè ní Adamu, tí ó wà ní tòsí Saretani; nígbà tí omi tí ń sàn lọ sínú Òkun aginjù (ti o túmọ̀ sí Òkun Iyọ̀) gé kúrò pátápátá. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kọjá sí òdìkejì ní ìdojúkọ Jeriko. 17Àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí Olúwa sì dúró ṣinṣin lórí ilẹ̀ gbígbẹ ní àárín Jordani, nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ń kọjá títí gbogbo orílẹ̀-èdè náà fi rékọjá nínú odò Jordani lórí ilẹ̀ gbígbẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.