Native Bible

Joshua 22:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Báyìí ni àwọn ẹ̀yà Reubeni, ẹ̀yà Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase fi àwọn ará Israẹli sílẹ̀ ní Ṣilo ní Kenaani láti padà sí Gileadi, ilẹ̀ wọn, èyí tí wọ́n ti gbà gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mose wá.

Joshua 22:9 in English

Joshua 22:9 · Berean Standard Bible

So the Reubenites, the Gadites, and the half-tribe of Manasseh left the Israelites at Shiloh in the land of Canaan to return to their own land of Gilead, which they had acquired according to the command of the LORD through Moses.

Context

7(Mose ti fi ilẹ̀ fún ìdajì ẹ̀yà Manase ní Baṣani, Joṣua sì ti fún ìdajì ẹ̀yà yòókù ní ilẹ̀ ní ìwọ̀-oòrùn Jordani, pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn). Joṣua súre fún wọn ó sì jẹ́ kí wọn máa lọ sí ilẹ̀ wọn, 8Ó sì wí pé, “Ẹ padà sí ilẹ̀ ẹ yín pẹ̀lú ọrọ̀ púpọ̀ yín, pẹ̀lú agbo ẹran ọ̀sìn, pẹ̀lú fàdákà, wúrà, idẹ àti irin, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ aṣọ, kí ẹ sì pín ìkógun tí ẹ rí gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀tá yín pẹ̀lú àwọn arákùnrin yín.” 9Báyìí ni àwọn ẹ̀yà Reubeni, ẹ̀yà Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase fi àwọn ará Israẹli sílẹ̀ ní Ṣilo ní Kenaani láti padà sí Gileadi, ilẹ̀ wọn, èyí tí wọ́n ti gbà gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mose wá. 10Nígbà tí wọ́n wá dé Geliloti ní ẹ̀bá Jordani ní ilẹ̀ Kenaani, àwọn ẹ̀yà Reubeni, ẹ̀yà Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase mọ pẹpẹ ńlá tí ó tóbi kan ní ẹ̀bá Jordani. 11Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ pé àwọn ọmọ Reubeni, àti àwọn ọmọ Gadi àti ìlàjì ẹ̀yà Manase mọ pẹpẹ kan dojúkọ ilẹ̀ Kenaani ní Geliloti ní ẹ̀bá Jordani ní ìhà kejì àwọn ọmọ Israẹli,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.