Joṣua 22:24
Joshua 22:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Bẹ́ẹ̀ kọ́! Àwa ṣe èyí ní ìbẹ̀rù pé ní ọjọ́ tí àwọn ọmọ yín yóò wí fún wa pé, ‘Kí ni ẹ̀yin ní ṣe pẹ̀lú Olúwa, Ọlọ́run Israẹli?
Joshua 22:24 in English
Joshua 22:24 · Berean Standard Bible
But in fact we have done this for fear that in the future your descendants might say to ours, ‘What have you to do with the LORD, the God of Israel?
Context
22Olúwa Ọlọ́run àwọn ọlọ́run! Olúwa Ọlọ́run àwọn ọlọ́run, Òun mọ̀, jẹ́ kí Israẹli pẹ̀lú kí ó mọ̀! Bí èyí bá wà ní ìṣọ̀tẹ̀ tàbí àìgbọ́ràn sí Olúwa, ẹ má ṣe gbà wa ní òní yìí. 23Bí àwa bá ti mọ pẹpẹ wa láti yí padà kúrò ní ọ̀dọ̀ Olúwa àti láti rú ẹbọ sísun àti ẹbọ oúnjẹ jíjẹ, tàbí ẹbọ àlàáfíà ní orí rẹ, kí Olúwa fún ara rẹ̀ gba ẹ̀san. 24“Bẹ́ẹ̀ kọ́! Àwa ṣe èyí ní ìbẹ̀rù pé ní ọjọ́ tí àwọn ọmọ yín yóò wí fún wa pé, ‘Kí ni ẹ̀yin ní ṣe pẹ̀lú Olúwa, Ọlọ́run Israẹli? 25Olúwa ti fi Jordani ṣe ààlà láàrín àwa àti ẹ̀yin—àwọn ọmọ Reubeni àti àwọn ọmọ Gadi! Ẹ kò ni ní ìpín nínú Olúwa.’ Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ yín lè mú kí àwọn ọmọ wa dẹ́kun láti máa bẹ̀rù Olúwa. 26“Nítorí èyí ni àwa ṣe wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí àwa múra láti mọ pẹpẹ kan, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún ẹbọ sísun, tàbí fún àwọn ìrúbọ.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.