Native Bible

Joshua 22:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Gbogbo àjọ ènìyàn Olúwa wí pe, ‘A fẹ́ mọ ìdí tí ẹ fi sẹ̀ sí Ọlọ́run Israẹli nípa yíyí padà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ tí ẹ sì kọ́ pẹpẹ ìṣọ̀tẹ̀ ní ìlòdì sí Olúwa?

Joshua 22:16 in English

Joshua 22:16 · Berean Standard Bible

“This is what the whole congregation of the LORD says: ‘What is this breach of faith you have committed today against the God of Israel by turning away from the LORD and building for yourselves an altar, that you might rebel against the LORD this day?

Context

14Pẹ̀lú rẹ̀ wọ́n rán àwọn ọkùnrin olóyè mẹ́wàá, ẹnìkan fún ẹ̀yà Israẹli kọ̀ọ̀kan, olórí ọ̀kọ̀ọ̀kan tiwọn jẹ́ olórí ìdílé láàrín àwọn ọmọ Israẹli. 15Nígbà tí wọ́n lọ sí Gileadi—sí Reubeni, Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase—wọ́n sì sọ fún wọn pé, 16“Gbogbo àjọ ènìyàn Olúwa wí pe, ‘A fẹ́ mọ ìdí tí ẹ fi sẹ̀ sí Ọlọ́run Israẹli nípa yíyí padà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ tí ẹ sì kọ́ pẹpẹ ìṣọ̀tẹ̀ ní ìlòdì sí Olúwa? 17Ẹ̀ṣẹ̀ Peori kò ha tó fún wa bí? Títí di òní yìí àwa kò tí ì wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àjàkálẹ̀-ààrùn ti jà láàrín ènìyàn Olúwa! 18Ṣé ẹ tún wá ń padà kúrò lẹ́yìn Olúwa ni báyìí? “ ‘Tí ẹ̀yin bá ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa ní òní, ní ọ̀la ní òun o bínú sí gbogbo ìpéjọpọ̀ Israẹli.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.