Native Bible

Joshua 21:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

(ìlú wọ̀nyí ni a fún àwọn ọmọ Aaroni tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú ìdílé Kohati tí í ṣe ọmọ Lefi, nítorí tí ìpín àkọ́kọ́ jẹ́ tiwọn).

Joshua 21:10 in English

Joshua 21:10 · Berean Standard Bible

to the descendants of Aaron from the Kohathite clans of the Levites, because the first lot fell to them:

Context

8Báyìí ni àwọn ọmọ Israẹli pín ìlú wọ̀nyí àti ilẹ̀ pápá oko tútù fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ láti ẹnu Mose. 9Láti ara ẹ̀yà Juda àti ẹ̀yà Simeoni ni wọ́n ti pín àwọn ìlú tí a dárúkọ wọ̀nyí, 10(ìlú wọ̀nyí ni a fún àwọn ọmọ Aaroni tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú ìdílé Kohati tí í ṣe ọmọ Lefi, nítorí tí ìpín àkọ́kọ́ jẹ́ tiwọn). 11Wọ́n fún wọn ní Kiriati-Arba (tí í ṣe, Hebroni), pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù tí ó yí wọn ká, ní ilẹ̀ òkè Juda. (Arba ni baba ńlá Anaki.) 12Ṣùgbọ́n àwọn oko àti àwọn abúlé ní agbègbè ìlú náà ni wọ́n ti fi fún Kalebu ọmọ Jefunne gẹ́gẹ́ bí ohun ìní rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.