Joṣua 17:6
Joshua 17:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
nítorí tí àwọn ọmọbìnrin ẹ̀yà Manase gba ìní ní àárín àwọn ọmọkùnrin. Ilẹ̀ Gileadi sì jẹ́ ti ìyókù àwọn ọmọ Manase.
Joshua 17:6 in English
Joshua 17:6 · Berean Standard Bible
because the daughters of Manasseh received an inheritance among his sons. And the land of Gilead belonged to the rest of the sons of Manasseh.
Context
4Wọ́n sì lọ bá Eleasari àlùfáà, Joṣua ọmọ Nuni, àti àwọn olórí wí pé, “Olúwa pàṣẹ fún Mose láti fún wa ní ìní ní àárín àwọn arákùnrin wa.” Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua fún wọn ní ìní pẹ̀lú àwọn arákùnrin baba wọn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa. 5Ìpín ilẹ̀ Manase sì jẹ́ ìsọ̀rí mẹ́wàá ní ẹ̀bá Gileadi àti Baṣani ìlà-oòrùn Jordani, 6nítorí tí àwọn ọmọbìnrin ẹ̀yà Manase gba ìní ní àárín àwọn ọmọkùnrin. Ilẹ̀ Gileadi sì jẹ́ ti ìyókù àwọn ọmọ Manase. 7Agbègbè Manase sì fẹ̀ láti Aṣeri títí dé Mikmeta ní ìlà-oòrùn Ṣekemu. Ààlà rẹ̀ sì lọ sí ìhà gúúsù títí tó fi dé ibi tí àwọn ènìyàn ń gbé ní Tapua, 8(Manase lo ni ilẹ̀ Tapua, ṣùgbọ́n Tapua fúnra rẹ̀ to wà ni ààlà ilẹ̀ Manase jẹ ti àwọn ará Efraimu.)
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.