Joṣua 15:7
Joshua 15:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ààlà náà gòkè lọ títí dé Debiri láti àfonífojì Akori, ó sì yípadà sí àríwá Gilgali, èyí tí ń bẹ ní iwájú òkè Adummimu, tí ń bẹ ní ìhà gúúsù odò náà. Ó sì tẹ̀síwájú sí apá omi En-Ṣemeṣi, ó sì jáde sí En-Rogeli.
Joshua 15:7 in English
Joshua 15:7 · Berean Standard Bible
Then the border went up to Debir from the Valley of Achor, turning north to Gilgal, which faces the Ascent of Adummim south of the ravine. It continued along the waters of En-shemesh and came out at En-rogel.
Context
5Ààlà wọn ní ìhà ìlà-oòrùn ní Òkun Iyọ̀ títí dé ẹnu Jordani.
Ààlà àríwá bẹ̀rẹ̀ láti etí òkun ní ẹnu Jordani, 6ààlà náà sì tún dé Beti-Hogla, ó sì lọ sí ìhà àríwá Beti-Araba. Ààlà náà sì tún dé ibi Òkúta Bohani ti ọmọ Reubeni. 7Ààlà náà gòkè lọ títí dé Debiri láti àfonífojì Akori, ó sì yípadà sí àríwá Gilgali, èyí tí ń bẹ ní iwájú òkè Adummimu, tí ń bẹ ní ìhà gúúsù odò náà. Ó sì tẹ̀síwájú sí apá omi En-Ṣemeṣi, ó sì jáde sí En-Rogeli. 8Ààlà náà sì tún gòkè lọ sí àfonífojì Beni-Hinnomu ní ìhà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ gúúsù ti Jebusi (tí í ṣe Jerusalẹmu). Ó sì gòkè lọ sí orí òkè tí ó wà lórí àfonífojì Hinnomu tí ń bẹ ní ìpẹ̀kun àfonífojì Refaimu ní ìhà àríwá. 9Ààlà náà sì lọ láti orí òkè lọ sí ìsun omi Nefitoa, ó sì jáde sí ìlú òkè Efroni, ó sì lọ sí apá ìsàlẹ̀ Baalahi (tí í ṣe, Kiriati-Jearimu).
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.