Native Bible

Joshua 14:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ǹjẹ́ nísinsin yìí, kíyèsi i Olúwa dá mi sí gẹ́gẹ́ bí ó ti wí, láti ọdún márùndínláàádọ́ta yìí wá, láti ìgbà tí Olúwa ti sọ ọ̀rọ̀ yìí fún Mose, nígbà tí Israẹli ń rìn kiri nínú aginjù, sì kíyèsi i nísinsin yìí, èmi nìyìí lónìí, ọmọ àrùndínláàdọ́rùn-ún ọdún.

Joshua 14:10 in English

Joshua 14:10 · Berean Standard Bible

Now behold, as the LORD promised, He has kept me alive these forty-five years since He spoke this word to Moses, while Israel wandered in the wilderness. So here I am today, eighty-five years old,

Context

8ṣùgbọ́n àwọn arákùnrin mi tí wọ́n bá mi lọ mú àyà àwọn ènìyàn já. Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi fi gbogbo ọkàn tẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run mi. 9Ní ọjọ́ náà, Mose búra fún mi pé, ‘Ilẹ̀ tí ẹsẹ̀ rẹ ti rìn ni yóò jẹ́ ìní rẹ àti ti àwọn ọmọ rẹ láéláé, nítorí pé ìwọ fi tọkàntọkàn wà pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run mi.’ 10“Ǹjẹ́ nísinsin yìí, kíyèsi i Olúwa dá mi sí gẹ́gẹ́ bí ó ti wí, láti ọdún márùndínláàádọ́ta yìí wá, láti ìgbà tí Olúwa ti sọ ọ̀rọ̀ yìí fún Mose, nígbà tí Israẹli ń rìn kiri nínú aginjù, sì kíyèsi i nísinsin yìí, èmi nìyìí lónìí, ọmọ àrùndínláàdọ́rùn-ún ọdún. 11Síbẹ̀ èmi ní agbára lónìí, bí ìgbà tí Mose rán mi jáde. Èmi sì ní agbára láti jáde fún ogun nísinsin yìí gẹ́gẹ́ bí mo ti wà ní ìgbà náà. 12Nísinsin yìí fi ìlú orí òkè fún mi èyí tí Olúwa ṣe ìlérí fún mi ní ọjọ́ náà. Ìwọ gbọ́ ní ìgbà náà pé àwọn ọmọ Anaki ti wà ní ibẹ̀, àti àwọn ìlú wọn tóbi, pé ó sì ṣe olódi, ṣùgbọ́n bí Olúwa ba fẹ́, èmi yóò lé wọn jáde, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.