Native Bible

Joshua 13:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbogbo ìlú Sihoni ọba àwọn Amori, tí ó ṣe àkóso ní Heṣboni, títí dé ààlà àwọn ará Ammoni.

Joshua 13:10 in English

Joshua 13:10 · Berean Standard Bible

and all the cities of Sihon king of the Amorites who reigned in Heshbon, as far as the border of the Ammonites;

Context

8Àwọn ìdajì ẹ̀yà Manase tí ó kù, àti àwọn Reubeni àti àwọn Gadi ti gba ilẹ̀ ìní, tí Mose ti fún wọn ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani bí Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti fi fún wọn. 9Ó sì lọ títí láti Aroeri tí ń bẹ létí àfonífojì Arnoni, àti láti ìlú náà tí ń bẹ ní àárín àfonífojì náà, àti pẹ̀lú gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Medeba títí dé Diboni. 10Gbogbo ìlú Sihoni ọba àwọn Amori, tí ó ṣe àkóso ní Heṣboni, títí dé ààlà àwọn ará Ammoni. 11Àti Gileadi, ní agbègbè àwọn ènìyàn Geṣuri àti Maakati, gbogbo òkè Hermoni àti gbogbo Baṣani títí dé Saleka, 12ìyẹn, gbogbo ilẹ̀ ọba Ogu ní Baṣani, tí ó jẹ ọba ní Aṣtarotu àti Edrei, ẹni tí ó kù nínú àwọn Refaimu ìyókù. Mose ti ṣẹ́gun wọn, ó sì ti gba ilẹ̀ wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.