Joṣua 11:3
Joshua 11:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
sí àwọn ará Kenaani ní ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn; sí àwọn Amori, Hiti, Peresi àti Jebusi ní orí òkè; àti sí àwọn Hifi ní ìsàlẹ̀ Hermoni ní agbègbè Mispa.
Joshua 11:3 in English
Joshua 11:3 · Berean Standard Bible
to the Canaanites in the east and west; to the Amorites, Hittites, Perizzites, and Jebusites in the hill country; and to the Hivites at the foot of Hermon in the land of Mizpah.
Context
1Nígbà tí Jabini ọba Hasori gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ó ránṣẹ́ sí Jobabu ọba Madoni, sí ọba Ṣimroni àti Akṣafu, 2àti sí àwọn ọba ìhà àríwá tí wọ́n wà ní orí òkè ní aginjù, gúúsù ti Kinnereti, ní ẹsẹ̀ òkè ìwọ̀-oòrùn àti ní Nafoti Dori ní ìwọ̀-oòrùn; 3sí àwọn ará Kenaani ní ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn; sí àwọn Amori, Hiti, Peresi àti Jebusi ní orí òkè; àti sí àwọn Hifi ní ìsàlẹ̀ Hermoni ní agbègbè Mispa. 4Wọ́n sì jáde pẹ̀lú gbogbo ogun wọn àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun ńlá, wọ́n sì pọ̀, gẹ́gẹ́ bí iyanrìn etí òkun. 5Gbogbo àwọn ọba yìí pa ọmọ-ogun wọn pọ̀, wọ́n sì pa ibùdó sí ibi omi Meromu láti bá Israẹli jà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.