Joṣua 11:22
Joshua 11:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kò sí ará Anaki kankan tí ó ṣẹ́kù ní ilẹ̀ Israẹli: bí kò ṣe ní Gasa, Gati àti Aṣdodu.
Joshua 11:22 in English
Joshua 11:22 · Berean Standard Bible
No Anakim were left in the land of the Israelites; only in Gaza, Gath, and Ashdod did any survive.
Context
20Nítorí Olúwa fúnra rẹ̀ ní ó sé ọkàn wọn le, kí wọn kí ó lè bá Israẹli jagun, kí òun lè pa wọ́n run pátápátá, kí wọn má sì ṣe rí ojúrere, ṣùgbọ́n kí ó lè pa wọ́n, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose. 21Ní àkókò náà ni Joṣua lọ tí ó sì run àwọn ará Anaki kúrò ní ilẹ̀ òkè, láti Hebroni, Debiri, àti ní Anabu, àti gbogbo ilẹ̀ Juda, àti kúrò ní gbogbo ilẹ̀ òkè Israẹli. Joṣua sì run gbogbo wọn pátápátá àti ìlú wọn. 22Kò sí ará Anaki kankan tí ó ṣẹ́kù ní ilẹ̀ Israẹli: bí kò ṣe ní Gasa, Gati àti Aṣdodu. 23Bẹ́ẹ̀ ní Joṣua sì gba gbogbo ilẹ̀ náà, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose, ó sì fi fún Israẹli ní ilẹ̀ ìní gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn nípa ẹ̀yà wọn.
Ilẹ̀ náà sì sinmi ogun.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.