Joṣua 10:39
Joshua 10:39 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n gba ìlú náà, ọba rẹ̀ àti gbogbo ìlú wọn, wọ́n sì fi idà pa wọ́n. Gbogbo ènìyàn inú rẹ̀ ni wọ́n parun pátápátá. Wọn kò sì dá ẹnìkankan sí. Wọ́n ṣe sí Debiri àti ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wọn ti ṣe sí Libina àti ọba rẹ̀ àti sí Hebroni.
Joshua 10:39 in English
Joshua 10:39 · Berean Standard Bible
And they captured Debir, its king, and all its villages. They put them to the sword and devoted to destruction everyone in the city, leaving no survivors. Joshua did to Debir and its king as he had done to Hebron and as he had done to Libnah and its king.
Context
37Wọ́n gba ìlú náà, wọ́n sì ti idà bọ̀ ọ́, pẹ̀lú ọba rẹ̀, gbogbo ìletò wọn àti gbogbo ènìyàn ibẹ̀. Wọn kò dá ẹnìkan sí. Gẹ́gẹ́ bí ti Egloni, wọ́n run un pátápátá àti gbogbo ènìyàn inú rẹ̀. 38Nígbà náà ni Joṣua àti gbogbo Israẹli tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ yí padà, wọ́n sì kọlu Debiri. 39Wọ́n gba ìlú náà, ọba rẹ̀ àti gbogbo ìlú wọn, wọ́n sì fi idà pa wọ́n. Gbogbo ènìyàn inú rẹ̀ ni wọ́n parun pátápátá. Wọn kò sì dá ẹnìkankan sí. Wọ́n ṣe sí Debiri àti ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wọn ti ṣe sí Libina àti ọba rẹ̀ àti sí Hebroni. 40Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua ṣẹ́gun gbogbo agbègbè náà, ìlú òkè, gúúsù, ìlú ẹsẹ̀ òkè ti ìhà ìwọ̀-oòrùn àti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè pẹ̀lú gbogbo ọba, wọn kò dá ẹnìkankan sí. Ó pa gbogbo ohun alààyè run pátápátá, gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run Israẹli, ti pàṣẹ. 41Joṣua sì ṣẹ́gun wọn láti Kadeṣi-Barnea sí Gasa àti láti gbogbo agbègbè Goṣeni lọ sí Gibeoni.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.