Native Bible

Joshua 10:36 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni Joṣua àti gbogbo Israẹli ṣí láti Egloni lọ sí Hebroni, wọ́n sì kọlù ú.

Joshua 10:36 in English

Joshua 10:36 · Berean Standard Bible

Then Joshua and all Israel with him went up from Eglon to Hebron and fought against it.

Context

34Nígbà náà ni Joṣua àti gbogbo Israẹli tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kọjá láti Lakiṣi lọ sí Egloni; wọ́n sì dó tì í, wọ́n sì kọlù ú. 35Wọ́n gbà á ní ọjọ́ náà, wọ́n sì fi ojú idà kọlù ú, wọ́n sì run gbogbo ènìyàn ibẹ̀ pátápátá, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe sí Lakiṣi. 36Nígbà náà ni Joṣua àti gbogbo Israẹli ṣí láti Egloni lọ sí Hebroni, wọ́n sì kọlù ú. 37Wọ́n gba ìlú náà, wọ́n sì ti idà bọ̀ ọ́, pẹ̀lú ọba rẹ̀, gbogbo ìletò wọn àti gbogbo ènìyàn ibẹ̀. Wọn kò dá ẹnìkan sí. Gẹ́gẹ́ bí ti Egloni, wọ́n run un pátápátá àti gbogbo ènìyàn inú rẹ̀. 38Nígbà náà ni Joṣua àti gbogbo Israẹli tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ yí padà, wọ́n sì kọlu Debiri.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.