Jona 3:9
Jonah 3:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ta ni ó lè mọ̀ bí Ọlọ́run yóò yípadà kí ó sì ronúpìwàdà, kí ó sì yípadà kúrò ní ìbínú gbígbóná rẹ̀, kí àwa má ṣègbé?”
Jonah 3:9 in English
Jonah 3:9 · Berean Standard Bible
Who knows? God may turn and relent; He may turn from His fierce anger, so that we will not perish.”
Context
7Nígbà náà ní ó kéde rẹ̀ ni Ninefe pé,
“Kí a la Ninefe já nípa àṣẹ ọba, àti àwọn àgbàgbà rẹ̀ pé:
“Má ṣe jẹ́ kí ènìyàn, tàbí ẹranko, ọ̀wọ́ ẹran tàbí agbo ẹran, tọ́ ohunkóhun wò, má jẹ́ kí wọn jẹ tàbí mu omi. 8Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ènìyàn àti ẹranko da aṣọ ọ̀fọ̀ bo ara, kí wọn sì kígbe kíkan sí Ọlọ́run, sì jẹ́ kí wọn yípadà, olúkúlùkù kúrò ní ọ̀nà ibi rẹ̀ àti kúrò ní ìwà ìpa tí ó wà lọ́wọ́ wọn. 9Ta ni ó lè mọ̀ bí Ọlọ́run yóò yípadà kí ó sì ronúpìwàdà, kí ó sì yípadà kúrò ní ìbínú gbígbóná rẹ̀, kí àwa má ṣègbé?” 10Ọlọ́run sì rí ìṣe wọn pé wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀nà ibi wọn, Ọlọ́run sì ronúpìwàdà ibi tí òun ti wí pé òun yóò ṣe sí wọn, òun kò sì ṣe e mọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.