Native Bible

Jonah 3:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jona sì dìde ó lọ sí Ninefe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa. Ninefe jẹ́ ìlú títóbi gidigidi, ó tó ìrìn ọjọ́ mẹ́ta.

Jonah 3:3 in English

Jonah 3:3 · Berean Standard Bible

This time Jonah got up and went to Nineveh, in accordance with the word of the LORD. Now Nineveh was an exceedingly great city,* requiring a three-day journey.*

Context

1Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jona wá nígbà kejì wí pé: 2“Dìde lọ sí Ninefe, ìlú ńlá a nì, kí o sì kéde sí i, ìkéde tí mo sọ fún ọ.” 3Jona sì dìde ó lọ sí Ninefe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa. Ninefe jẹ́ ìlú títóbi gidigidi, ó tó ìrìn ọjọ́ mẹ́ta. 4Jona sì bẹ̀rẹ̀ sí wọ ìlú náà lọ ní ìrìn ọjọ́ kan, ó sì ń kéde, ó sì wí pé, “Níwọ́n ogójì ọjọ́ sí i, a ó bi Ninefe wó.” 5Àwọn ènìyàn Ninefe sì gba Ọlọ́run gbọ́. Wọ́n sì kéde àwẹ̀, gbogbo wọ́n sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, bẹ̀rẹ̀ láti orí ọmọdé títí dé orí àgbà wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.