Native Bible

Jonah 2:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Nígbà tí ó rẹ ọkàn mi nínú mi, èmi rántí rẹ, Olúwa, àdúrà mi sì wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, nínú tẹmpili mímọ́ rẹ.

Jonah 2:7 in English

Jonah 2:7 · Berean Standard Bible

As my life was fading away, I remembered the LORD. My prayer went up to You, to Your holy temple.

Context

5Omi yí mi káàkiri, àní títí dé ọkàn; ibú yí mi káàkiri, a fi koríko odò wé mi lórí. 6Èmi sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ àwọn òkè ńlá; ilẹ̀ ayé pẹ̀lú ìdènà rẹ̀ yí mi ká títí: ṣùgbọ́n ìwọ ti mú ẹ̀mí mi wá sókè láti inú ibú wá, Olúwa Ọlọ́run mi. 7“Nígbà tí ó rẹ ọkàn mi nínú mi, èmi rántí rẹ, Olúwa, àdúrà mi sì wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, nínú tẹmpili mímọ́ rẹ. 8“Àwọn tí ń fàmọ́ òrìṣà èké kọ àánú ara wọn sílẹ̀. 9Ṣùgbọ́n èmi yóò fi orin ọpẹ́, rú ẹbọ sí ọ. Èmi yóò san ẹ̀jẹ́ tí mo ti jẹ́. ‘Ìgbàlà wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa.’ ”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.