Native Bible

Joel 1:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí orílẹ̀-èdè kan ti ṣígun sí ilẹ̀ mìíràn ó ní agbára púpọ̀, kò sì ní òǹkà; ó ní eyín kìnnìún ó sì ní èrìgì abo kìnnìún.

Joel 1:6 in English

Joel 1:6 · Berean Standard Bible

For a nation has invaded My land, powerful and without number; its teeth are the teeth of a lion, and its fangs are the fangs of a lioness.

Context

4Èyí tí eṣú tí agénijẹ jẹ kù ní ọ̀wọ́ eṣú ńlá ńlá ti jẹ, èyí tí ọ̀wọ́ eṣú ńlá ńlá jẹ kù ní eṣú kéékèèké jẹ, èyí tí eṣú kéékèèké jẹ kù ni eṣú apanirun mìíràn jẹ. 5Ẹ jí gbogbo ẹ̀yin ọ̀mùtí kí ẹ sì sọkún ẹ hu gbogbo ẹ̀yin ọ̀mu-wáìnì; ẹ hu nítorí wáìnì tuntun nítorí a gbà á kúrò lẹ́nu yín. 6Nítorí orílẹ̀-èdè kan ti ṣígun sí ilẹ̀ mìíràn ó ní agbára púpọ̀, kò sì ní òǹkà; ó ní eyín kìnnìún ó sì ní èrìgì abo kìnnìún. 7Ó ti pa àjàrà mi run, ó sì ti ya ẹ̀ka igi ọ̀pọ̀tọ́ mi kúrò, ó ti bò èèpo rẹ̀ jálẹ̀, ó sì sọ ọ́ nù; àwọn ẹ̀ka rẹ̀ ni a sì sọ di funfun. 8Ẹ pohùnréré ẹkún bí wúńdíá tí a fi aṣọ ọ̀fọ̀ dí ni àmùrè, nítorí ọkọ ìgbà èwe rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.