Jobu 9:24
Job 9:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí a bá fi ayé lé ọwọ́ ènìyàn búburú; ó sì bo àwọn onídàájọ́ rẹ̀ lójú; bí kò bá rí bẹ́ẹ̀ ǹjẹ́ ta ni?
Job 9:24 in English
Job 9:24 · Berean Standard Bible
The earth is given into the hand of the wicked; He blindfolds its judges. If it is not He, then who is it?
Context
22Ohùn kan náà ni, nítorí náà ni èmi ṣe sọ:
‘Òun a pa ẹni òtítọ́ àti ènìyàn búburú pẹ̀lú.’ 23Bí ìjàǹbá bá pa ni lójijì,
yóò rẹ́rìn-ín nínú ìdààmú aláìṣẹ̀. 24Nígbà tí a bá fi ayé lé ọwọ́ ènìyàn búburú;
ó sì bo àwọn onídàájọ́ rẹ̀ lójú;
bí kò bá rí bẹ́ẹ̀ ǹjẹ́ ta ni? 25“Ǹjẹ́ nísinsin yìí ọjọ́ mi yára ju oníṣẹ́ lọ,
wọ́n fò lọ, wọn kò rí ayọ̀. 26Wọ́n kọjá lọ bí ọkọ̀ eèsún papirusi tí ń sáré lọ;
bí idì tí ń yára si ohùn ọdẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.