Jobu 40
Job 40 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
1Olúwa dá Jobu lóhùn sí pẹ̀lú, ó sì wí pé, 2“Ẹni tí ń bá Olódùmarè wíjọ́ yóò ha kọ ní ẹ̀kọ́?
Ẹni tí ń bá Ọlọ́run wí jẹ́ kí ó dáhùn!” 3Nígbà náà ni Jobu dá Olúwa lóhùn wá ó sì wí pé, 4“Kíyèsi i, ẹ̀gbin ni èmi—ohun kí ni èmi ó dà?
Èmi ó fi ọwọ́ mi le ẹnu mi. 5Ẹ̀ẹ̀kan ní mo sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n èmi kì yóò tún sọ mọ́;
lẹ́ẹ̀kejì ni, èmi kò sì le ṣe é mọ́.” 6Nígbà náà ní Olúwa dá Jobu lóhùn láti inú ìjì àyíká wá, ó sì wí pé, 7“Di àmùrè gírí ní ẹgbẹ́ rẹ bí ọkùnrin,
èmi ó bi ọ léèrè,
kí ìwọ kí ó sì dá mi lóhùn. 8“Ìwọ ha fẹ́ mú ìdájọ́ mi di asán?
Ìwọ ó sì dá mi lẹ́bi, kí ìwọ lè ṣe olódodo. 9Ìwọ ni apá bí Ọlọ́run
tàbí ìwọ lè fi ohùn sán àrá bí òun? 10Fi ọláńlá àti ọlá ìtayọ rẹ̀ ṣe ara rẹ ní ọ̀ṣọ́,
tí ó sì fi ògo àti títóbi ọ̀ṣọ́ bo ara ní aṣọ. 11Mú ìrunú ìbínú rẹ jáde;
kíyèsí gbogbo ìwà ìgbéraga rẹ kí o sì rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀. 12Wo gbogbo ìwà ìgbéraga, ènìyàn kí o sì rẹ ẹ sílẹ̀
kí o sì tẹ ènìyàn búburú mọ́lẹ̀ ní ipò wọn. 13Sin gbogbo wọn papọ̀ nínú erùpẹ̀,
kí o sì di ojú ìkọ̀kọ̀ wọn ní isà òkú. 14Nígbà náà ní èmi ó yìn ọ́ pé,
ọwọ́ ọ̀tún ara rẹ lè gbà ọ́ là. 15“Ǹjẹ́ nísinsin yìí kíyèsi Behemoti,
tí mo dá pẹ̀lú rẹ,
òun a máa jẹ koríko bí ọ̀dá màlúù. 16Wò o nísinsin yìí, agbára rẹ wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ,
àti ipa rẹ nínú ìṣàn ìkún rẹ. 17Òun a máa jù ìrù rẹ̀ bí i igi kedari,
iṣan itan rẹ̀ dìjọ pọ̀. 18Egungun rẹ̀ ní ògùṣọ̀ idẹ,
Egungun rẹ̀ dàbí ọ̀pá irin. 19Òun ni olórí nínú àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run;
síbẹ̀ Ẹlẹ́dàá rẹ̀ fi idà rẹ̀ lé e lọ́wọ́. 20Nítòótọ́ òkè ńlá ńlá ní i mu ohun jíjẹ fún un wá,
níbi tí gbogbo ẹranko igbó máa ṣiré ní ẹ̀gbẹ́ ibẹ̀. 21Ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi lótusì,
lábẹ́ eèsún àti ẹrẹ̀. 22Igi lótusì síji wọn bò o;
igi arọrọ odò yí i káàkiri. 23Kíyèsi i, odò ńlá sàn jọjọ, òun kò sálọ;
ó wà láìléwu bí ó bá ṣe pé odò Jordani ti ṣàn lọ sí ẹnu rẹ̀. 24Ẹnìkan ha lè mú un ní ojú rẹ̀,
tàbí dẹkùn fún tàbí a máa fi ọ̀kọ̀ gún imú rẹ̀?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.