Jobu 4:6
Job 4:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìbẹ̀rù Ọlọ́run rẹ kò ha jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ àti ìdúró ọ̀nà rẹ kò ha sì jẹ́ ìrètí rẹ?
Job 4:6 in English
Job 4:6 · Berean Standard Bible
Is your reverence not your confidence, and the uprightness of your ways your hope?
Context
4Ọ̀rọ̀ rẹ ti gbé àwọn tí ń ṣubú lọ dúró,
ìwọ sì ti mú eékún àwọn tí ń wárìrì lera. 5Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ó dé bá ọ, ó sì rẹ̀ ọ́, ó kọlù ọ́;
ara rẹ kò lélẹ̀. 6Ìbẹ̀rù Ọlọ́run rẹ kò ha jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ
àti ìdúró ọ̀nà rẹ kò ha sì jẹ́ ìrètí rẹ? 7“Èmi bẹ̀ ọ́ rántí, ta ni ó ṣègbé rí láìṣẹ̀?
Tàbí níbo ni a gbé gé olódodo kúrò rí? 8Àní bí èmi ti rí i pé, àwọn tí ń ṣe ìtulẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀,
tí wọ́n sì fún irúgbìn ìwà búburú, wọn a sì ká èso rẹ̀ náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.