Native Bible

Job 31:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

(jẹ́ kí Ọlọ́run wọ́n mí nínú ìwọ̀n òdodo, kí Ọlọ́run le mọ ìdúró ṣinṣin mi.)

Job 31:6 in English

Job 31:6 · Berean Standard Bible

let God weigh me with honest scales, that He may know my integrity.

Context

4Òun kò ha ri ipa ọ̀nà mi, òun kò ha sì ka gbogbo ìṣísẹ̀ mi? 5“Bí ó bá ṣe pé èmi bá fi àìṣòótọ́ rìn, tàbí tí ẹsẹ̀ mi sì yára sí ẹ̀tàn, 6(jẹ́ kí Ọlọ́run wọ́n mí nínú ìwọ̀n òdodo, kí Ọlọ́run le mọ ìdúró ṣinṣin mi.) 7Bí ẹsẹ̀ mí bá yà kúrò lójú ọ̀nà, tí àyà mí sì tẹ̀lé ipa ojú mi, tàbí bí àbàwọ́n kan bá sì lẹ̀ mọ́ mi ní ọwọ́, 8ǹjẹ́ kí èmi kí ó gbìn kí ẹlòmíràn kí ó sì mújẹ, àní kí a fa irú-ọmọ mi tu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.