Jobu 21:31
Job 21:31 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ta ni yóò tako ipa ọ̀nà rẹ̀ lójúkojú, ta ni yóò sì san án padà fún un ní èyí tí ó ti ṣe?
Job 21:31 in English
Job 21:31 · Berean Standard Bible
Who denounces his behavior to his face? Who repays him for what he has done?
Context
29Ẹ̀yin kò béèrè lọ́wọ́ àwọn tí ń kọjá lọ ní ọ̀nà?
Ẹ̀yin kò mọ̀ àmì wọn, 30pé ènìyàn búburú ní a fi pamọ́ fún ọjọ́ ìparun.
A ó sì mú wọn jáde ní ọjọ́ ríru ìbínú. 31Ta ni yóò tako ipa ọ̀nà rẹ̀ lójúkojú,
ta ni yóò sì san án padà fún un ní èyí tí ó ti ṣe? 32Síbẹ̀ a ó sì sin ín ní ọ̀nà ipò òkú,
a ó sì máa ṣọ́ ibojì òkú. 33Ògúlùtu àfonífojì yóò dùn mọ́ ọn.
Gbogbo ènìyàn yóò sì máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn,
bí ènìyàn àìníye ti lọ síwájú rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.