Native Bible

Job 21:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ìgbà mélòó mélòó ní a ń pa fìtílà ènìyàn búburú kú? Ìgbà mélòó mélòó ní ìparun wọn dé bá wọn, tí Ọlọ́run sì í máa pín ìbìnújẹ́ nínú ìbínú rẹ̀?

Job 21:17 in English

Job 21:17 · Berean Standard Bible

How often is the lamp of the wicked put out? Does disaster come upon them? Does God, in His anger, apportion destruction?

Context

15Kí ni Olódùmarè tí àwa ó fi máa sìn in? Èrè kí ni a ó sì jẹ bí àwa ba gbàdúrà sí i? 16Kíyèsi i, àlàáfíà wọn kò sí nípa ọwọ́ wọn; ìmọ̀ ènìyàn búburú jìnnà sí mi réré. 17“Ìgbà mélòó mélòó ní a ń pa fìtílà ènìyàn búburú kú? Ìgbà mélòó mélòó ní ìparun wọn dé bá wọn, tí Ọlọ́run sì í máa pín ìbìnújẹ́ nínú ìbínú rẹ̀? 18Wọ́n dàbí àgékù koríko níwájú afẹ́fẹ́, àti bí ìyàngbò, tí ẹ̀fúùfù ńlá fẹ́ lọ. 19Ẹ̀yin wí pé, ‘Ọlọ́run to ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jọ fún àwọn ọmọ rẹ̀.’ Jẹ́ kí ó san án fún un, yóò sì mọ̀ ọ́n.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.