Native Bible

Job 2:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n nawọ́ rẹ nísinsin yìí, kí ó tọ́ egungun rẹ̀ àti ara rẹ̀, bí kì yóò sì bọ́hùn ní ojú rẹ.”

Job 2:5 in English

Job 2:5 · Berean Standard Bible

But stretch out Your hand and strike his flesh and bones, and he will surely curse You to Your face.”

Context

3Olúwa sì wí fún Satani pé, “Ìwọ ha kíyèsi Jobu ìránṣẹ́ mi, pé, kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ̀ ní ayé, ọkùnrin tí ń ṣe olóòtítọ́ tí ó sì dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì kórìíra ìwà búburú, bẹ́ẹ̀ ni ó sì di ìwà òtítọ́ rẹ̀ mu ṣinṣin, bí ìwọ tilẹ̀ ti dẹ mí sí i láti run ún láìnídìí.” 4Satani sì dá Olúwa lóhùn wí pé, “Awọ fún awọ; àní ohun gbogbo tí ènìyàn ní, òun ni yóò fi ra ẹ̀mí rẹ̀. 5Ṣùgbọ́n nawọ́ rẹ nísinsin yìí, kí ó tọ́ egungun rẹ̀ àti ara rẹ̀, bí kì yóò sì bọ́hùn ní ojú rẹ.” 6Olúwa sì wí fún Satani pé, “Wò ó, ó ń bẹ ní ìkáwọ́ rẹ, ṣùgbọ́n dá ẹ̀mí rẹ̀ sí.” 7Bẹ́ẹ̀ ni Satani jáde lọ kúrò níwájú Olúwa, ó sì sọ Jobu ní oówo kíkankíkan láti àtẹ́lẹsẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.