Native Bible

Job 17:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹni tí ó sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn dídún fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ fún èrè, òun ni ojú àwọn ọmọ rẹ̀ yóò mú òfo.

Job 17:5 in English

Job 17:5 · Berean Standard Bible

If a man denounces his friends for a price, the eyes of his children will fail.

Context

3“Fi fún mi Olúwa, ìlérí tí ìwọ fẹ́; ta ni yóò le ṣe ààbò fún mi? 4Nítorí pé ìwọ ti sé wọ́n láyà kúrò nínú òye; nítorí náà ìwọ kì yóò gbé wọn lékè. 5Ẹni tí ó sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn dídún fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ fún èrè, òun ni ojú àwọn ọmọ rẹ̀ yóò mú òfo. 6“Ọlọ́run ti sọ mi di ẹni òwe fún àwọn ènìyàn; níwájú wọn ni mo dàbí ẹni ìtutọ́ sí ní ojú. 7Ojú mí ṣú bàìbàì nítorí ìbìnújẹ́, gbogbo ẹ̀yà ara mi sì dàbí òjìji.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.