Jobu 14
Job 14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
1“Ènìyàn tí a bí nínú obìnrin,
ọlọ́jọ́ díẹ̀ ni, ó sì kún fún ìpọ́njú. 2Ó jáde wá bí ìtànná ewéko, a sì ké e lulẹ̀;
ó sì ń fò lọ bí òjìji, kò sì dúró pẹ́. 3Ìwọ sì ń síjú rẹ wò irú èyí ni?
Ìwọ sì mú mi wá sínú ìdájọ́ pẹ̀lú rẹ? 4Ta ni ó lè mú ohun mímọ́ láti inú àìmọ́ jáde wá?
Kò sí ẹnìkan! 5Ǹjẹ́ a ti pinnu ọjọ́ rẹ̀,
iye oṣù rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ,
ìwọ ti pààlà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní òun kò le kọjá rẹ̀. 6Yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kí ó lè sinmi,
títí yóò fi pé ọjọ́ rẹ̀ bí alágbàṣe. 7“Nítorí pé ìrètí wà fún igi, bí a bá
ké e lulẹ̀, pé yóò sì tún sọ,
àti pé ẹ̀ka rẹ̀ tuntun kì yóò gbẹ. 8Bí gbòǹgbò rẹ̀ tilẹ̀ di ogbó nínú ilẹ̀,
tí kùkùté rẹ̀ si kú ni ilẹ̀, 9síbẹ̀ nígbà tí ó bá gbóòórùn omi,
yóò sọ, yóò sì yọ ẹ̀ka jáde bí irúgbìn. 10Ṣùgbọ́n ènìyàn kú, a sì dàánù,
àní ènìyàn jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́: Òun kò sì sí mọ́. 11“Bí omi ti í tán nínú ipa odò,
àti bí odò ṣì tí í fà tí sì gbẹ, 12bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn dùbúlẹ̀ tí kò sì dìde mọ́;
títí ọ̀run kì yóò fi sí mọ́,
wọ́n kì yóò jí, a kì yóò jí wọn kúrò lójú oorun wọn. 13“Háà! ìwọ ìbá fi mí pamọ́ ní ipò òkú,
kí ìwọ kí ó fi mí pamọ́ ní ìkọ̀kọ̀,
títí ìbínú rẹ yóò fi rékọjá,
ìwọ ìbá lànà ìgbà kan sílẹ̀ fún mi, kí ó si rántí mi! 14Bí ènìyàn bá kú yóò sì tún yè bí?
Gbogbo ọjọ́ ìgbà tí a là sílẹ̀
fún mi ni èmi dúró dè, títí àmúdọ̀tún mi yóò fi dé. 15Ìwọ ìbá pè, èmi ìbá sì dá ọ lóhùn;
ìwọ ó sì ní ìfẹ́ sì iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. 16Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìwọ ń kaye ìṣísẹ̀ mi;
ìwọ kò fa ọwọ́ rẹ kúrò nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mi? 17A fi èdìdì di ìrékọjá mi sínú àpò,
ìwọ sì rán àìṣedéédéé mi pọ̀. 18“Àti nítòótọ́ òkè ńlá tí ó ṣubú, ó dasán,
a sì ṣí àpáta kúrò ní ipò rẹ̀. 19Omi a máa yinrin òkúta, ìwọ a sì
mú omi sàn bo ohun tí ó hù jáde lórí ilẹ̀,
ìwọ sì sọ ìrètí ènìyàn dí òfo. 20Ìwọ ṣẹ́gun rẹ̀ láéláé, òun sì kọjá lọ!
Ìwọ pa awọ ojú rẹ̀ dà, o sì rán an lọ kúrò. 21Àwọn ọmọ rẹ̀ bọ́ sí ipò ọlá, òun kò sì mọ̀;
wọ́n sì rẹ̀ sílẹ̀, òun kò sì kíyèsi i lára wọn. 22Ṣùgbọ́n ẹran-ara rẹ̀ ni yóò rí ìrora
ọkàn rẹ̀ ni yóò sì máa ní ìbìnújẹ́ nínú rẹ̀.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.