Johanu 9:22
John 9:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn òbí rẹ̀ sọ, nítorí tí wọ́n bẹ̀rù àwọn Júù: nítorí àwọn Júù ti fohùn ṣọ̀kan pé bí ẹnìkan bá jẹ́wọ́ pé Kristi ni, wọn ó yọ ọ́ kúrò nínú Sinagọgu.
John 9:22 in English
John 9:22 · Berean Standard Bible
His parents said this because they were afraid of the Jews. For the Jews had already determined that anyone who confessed Jesus as the Christ would be put out of the synagogue.
Context
20Àwọn òbí rẹ̀ dá wọn lóhùn wí pé, “Àwa mọ̀ pé ọmọ wa ni èyí, àti pé a bí i ní afọ́jú, 21ṣùgbọ́n bí ó tí ṣe ń ríran nísinsin yìí àwa kò mọ̀, ẹni tí ó là á lójú, àwa kò mọ̀, ẹni tí ó ti dàgbà ni òun; ẹ bi í léèrè, yóò wí fúnra rẹ̀.” 22Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn òbí rẹ̀ sọ, nítorí tí wọ́n bẹ̀rù àwọn Júù: nítorí àwọn Júù ti fohùn ṣọ̀kan pé bí ẹnìkan bá jẹ́wọ́ pé Kristi ni, wọn ó yọ ọ́ kúrò nínú Sinagọgu. 23Nítorí èyí ni àwọn òbí rẹ̀ fi wí pé, “Ẹni tí ó dàgbà ni òun, ẹ bi í léèrè.” 24Nítorí náà, wọ́n pe ọkùnrin afọ́jú náà lẹ́ẹ̀kejì, wọ́n sì wí fún un pé, “Fi ògo fún Ọlọ́run, àwa mọ̀ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ọkùnrin yìí jẹ́.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.