Johanu 9:10
John 9:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Bá wo ni ojú rẹ ṣe là?”
John 9:10 in English
John 9:10 · Berean Standard Bible
“How then were your eyes opened?” they asked.
Context
8Ǹjẹ́ àwọn aládùúgbò àti àwọn tí ó rí i nígbà àtijọ́ pé alágbe ni ó jẹ́, wí pé, “Ẹni tí ó ti ń jókòó ṣagbe kọ́ yìí?” 9Àwọn kan wí pé òun ni.
Àwọn ẹlòmíràn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ó jọ ọ́ ni.”
Ṣùgbọ́n òun wí pé, “Èmi ni.” 10Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Bá wo ni ojú rẹ ṣe là?” 11Ó dáhùn ó sì wí fún un pé, “Ọkùnrin kan tí a ń pè ní Jesu ni ó ṣe amọ̀, ó sì fi kun ojú mí, ó sì wí fún mi pé, Lọ sí adágún Siloamu, kí o sì wẹ̀, èmi sì lọ, mo wẹ̀, mo sì ríran.” 12Wọ́n sì wí fún un pé, “Òun náà ha dà?”
Ó sì wí pé, “Èmi kò mọ̀.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.