Native Bible

John 8:53 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ ha pọ̀ ju Abrahamu Baba wa lọ, ẹni tí ó kú? Àwọn wòlíì sì kú, ta ni ìwọ ń fi ara rẹ pè?”

John 8:53 in English

John 8:53 · Berean Standard Bible

Are You greater than our father Abraham? He died, as did the prophets. Who do You claim to be?”

Context

51Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí ẹnìkan bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kì yóò rí ikú láéláé.” 52Àwọn Júù wí fún un pé, “Nígbà yìí ni àwa mọ̀ pé ìwọ ní ẹ̀mí èṣù. Abrahamu kú, àti àwọn wòlíì; ìwọ sì wí pé, ‘Bí ẹnìkan bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kì yóò tọ́ ikú wò láéláé.’ 53Ìwọ ha pọ̀ ju Abrahamu Baba wa lọ, ẹni tí ó kú? Àwọn wòlíì sì kú, ta ni ìwọ ń fi ara rẹ pè?” 54Jesu dáhùn wí pé, “Bí mo bá yin ara mi lógo, ògo mi kò jẹ́ nǹkan, Baba mi ni ẹni tí ń yìn mí lógo, ẹni tí ẹ̀yin wí pé, Ọlọ́run yín ní i ṣe. 55Ẹ kò sì mọ̀ ọ́n, ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n, bí mo bá sì wí pé, èmi kò mọ̀ ọ́n, èmi yóò di èké gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin, ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n, mo sì pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.