Johanu 8:46
John 8:46 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ta ni nínú yín tí ó ti dá mi lẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀? Bí mo bá ń ṣọ òtítọ́, èéṣe tí ẹ̀yin kò fi gbà mí gbọ́?
John 8:46 in English
John 8:46 · Berean Standard Bible
Which of you can prove Me guilty of sin? If I speak the truth, why do you not believe Me?
Context
44Ti èṣù baba yin ni ẹ̀yin jẹ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ baba yín ni ẹ sì ń fẹ́ ṣe. Apànìyàn ni òun jẹ́ láti àtètèkọ́ṣe, kò sì dúró nínú òtítọ́; nítorí tí kò sí òtítọ́ nínú rẹ̀. Nígbà tí ó bá ń ṣèké, nínú ohun tirẹ̀ ni ó ń sọ nítorí èké ni, àti baba èké. 45Ṣùgbọ́n nítorí tí èmi ń sọ òtítọ́ fún yín, ẹ̀yin kò sì gbà mí gbọ́. 46Ta ni nínú yín tí ó ti dá mi lẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀? Bí mo bá ń ṣọ òtítọ́, èéṣe tí ẹ̀yin kò fi gbà mí gbọ́? 47Ẹni tí ń ṣe ti Ọlọ́run, a máa gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, nítorí èyí ni ẹ̀yin kò ṣe gbọ́, nítorí ẹ̀yin kì í ṣe ti Ọlọ́run.” 48Àwọn Júù dáhùn wọ́n sì wí fún un pé, “Àwa kò wí nítòótọ́ pé, ará Samaria ni ìwọ jẹ́, àti pé ìwọ ní ẹ̀mí èṣù?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.