Johanu 8:26
John 8:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mo ní ohun púpọ̀ láti sọ, àti láti ṣe ìdájọ́ nípa yín, ṣùgbọ́n olóòtítọ́ ni ẹni tí ó rán mi, ohun tí èmi sì ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá, wọ̀nyí ni èmi ń sọ fún aráyé.”
John 8:26 in English
John 8:26 · Berean Standard Bible
“I have much to say about you and much to judge. But the One who sent Me is truthful, and what I have heard from Him, I tell the world.”
Context
24Nítorí náà ni mo ṣe wí fún yín pé, ẹ ó kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín, nítorí bí kò ṣe pé ẹ bá gbàgbọ́ pé èmi ni, ẹ ó kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín.” 25Nítorí náà wọ́n wí fún un pé, “Ta ni ìwọ jẹ́?”
Jesu sì wí fún un pé, “Èmi ni èyí tí mo ti wí fún yín ní àtètèkọ́ṣe. 26Mo ní ohun púpọ̀ láti sọ, àti láti ṣe ìdájọ́ nípa yín, ṣùgbọ́n olóòtítọ́ ni ẹni tí ó rán mi, ohun tí èmi sì ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá, wọ̀nyí ni èmi ń sọ fún aráyé.” 27Kò yé wọn pé ti Baba ni ó ń sọ fún wọn. 28Lẹ́yìn náà Jesu wí fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ mọ̀ pé, nígbà tí ẹ bá gbé Ọmọ Ènìyàn sókè, nígbà náà ni ẹ ó mọ̀ pé èmi ni àti pé èmi kò dá ohunkóhun ṣe fún ara mi, ṣùgbọ́n bí Baba ti kọ́ mi, èmí ń sọ nǹkan wọ̀nyí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.