Johanu 7:35
John 7:35 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà ni àwọn Júù ń bá ara wọn sọ pé, “Níbo ni ọkùnrin yìí yóò gbé lọ tí àwa kì yóò fi rí i? Yóò ha lọ sí àárín àwọn Helleni tí wọ́n fọ́n káàkiri, kí ó sì máa kọ́ àwọn Helleni bí.
John 7:35 in English
John 7:35 · Berean Standard Bible
At this, the Jews said to one another, “Where does He intend to go that we will not find Him? Will He go where the Jews are dispersed among the Greeks,* and teach the Greeks?
Context
33Nítorí náà Jesu wí fún wọn pé, “Níwọ́n ìgbà díẹ̀ ni èmi yóò wà pẹ̀lú yín, èmi yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó rán mi. 34Ẹ̀yin yóò wá mi, ẹ̀yin kì yóò sì rí mi, àti ibi tí èmi bá wà, ẹ̀yin kì yóò le wà.” 35Nítorí náà ni àwọn Júù ń bá ara wọn sọ pé, “Níbo ni ọkùnrin yìí yóò gbé lọ tí àwa kì yóò fi rí i? Yóò ha lọ sí àárín àwọn Helleni tí wọ́n fọ́n káàkiri, kí ó sì máa kọ́ àwọn Helleni bí. 36Ọ̀rọ̀ kín ni èyí tí ó sọ yìí, ‘Ẹ̀yin yóò wá mi, ẹ kì yóò sì rí mi,’ àti ‘Ibi tí èmi bá wà ẹ̀yin kì yóò le wà’?” 37Lọ́jọ́ tó kẹ́yìn, tí í ṣe ọjọ́ ńlá àjọ, Jesu dúró, ó sì kígbe wí pé, “Bí òǹgbẹ bá ń gbẹ ẹnikẹ́ni, kí ó tọ̀ mí wá, kí ó sì mu.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.