Johanu 7:31
John 7:31 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọ̀pọ̀ nínú ìjọ ènìyàn sì gbà á gbọ́, wọ́n sì wí pé, “Nígbà tí Kristi náà bá dé, yóò ha ṣe iṣẹ́ àmì jù wọ̀nyí, tí ọkùnrin yìí ti ṣe lọ?”
John 7:31 in English
John 7:31 · Berean Standard Bible
Many in the crowd, however, believed in Him and said, “When the Christ comes, will He perform more signs than this man?”
Context
29Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n, nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ̀ ni mo ti wá, òun ni ó rán mi.” 30Nítorí náà wọ́n ń wá ọ̀nà à ti mú un, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbé ọwọ́ lé e, nítorí tí wákàtí rẹ̀ kò tí ì dé. 31Ọ̀pọ̀ nínú ìjọ ènìyàn sì gbà á gbọ́, wọ́n sì wí pé, “Nígbà tí Kristi náà bá dé, yóò ha ṣe iṣẹ́ àmì jù wọ̀nyí, tí ọkùnrin yìí ti ṣe lọ?” 32Àwọn Farisi gbọ́ pé, ìjọ ènìyàn ń sọ nǹkan wọ̀nyí lábẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀; àwọn Farisi àti àwọn olórí àlùfáà sì rán àwọn oníṣẹ́ lọ láti mú un. 33Nítorí náà Jesu wí fún wọn pé, “Níwọ́n ìgbà díẹ̀ ni èmi yóò wà pẹ̀lú yín, èmi yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó rán mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.