Native Bible

John 7:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n àwa mọ ibi tí ọkùnrin yí gbé ti wá, ṣùgbọ́n nígbà tí Kristi bá dé, kò sí ẹni tí yóò mọ ibi tí ó gbé ti wá.”

John 7:27 in English

John 7:27 · Berean Standard Bible

But we know where this man is from. When the Christ comes, no one will know where He is from.”

Context

25Nígbà náà ni àwọn kan nínú àwọn ará Jerusalẹmu wí pé, “Ẹni tí wọ́n ń wá ọ̀nà láti pa kọ́ yìí? 26Sì wò ó, ó ń sọ̀rọ̀ ní gbangba, wọn kò sì wí nǹkan kan sí i. Àwọn olórí ha mọ̀ nítòótọ́ pé, èyí ni Kristi náà? 27Ṣùgbọ́n àwa mọ ibi tí ọkùnrin yí gbé ti wá, ṣùgbọ́n nígbà tí Kristi bá dé, kò sí ẹni tí yóò mọ ibi tí ó gbé ti wá.” 28Nígbà náà ni Jesu kígbe ní tẹmpili bí ó ti ń kọ́ni, wí pé, “Ẹ̀yin mọ̀ mí, ẹ sì mọ ibi tí mo ti wá, èmi kò sì wá fún ara mi, ṣùgbọ́n olóòtítọ́ ni ẹni tí ó rán mi, ẹni tí ẹ̀yin kò mọ̀. 29Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n, nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ̀ ni mo ti wá, òun ni ó rán mi.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.