Johanu 6:58
John 6:58 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èyí sì ni oúnjẹ náà tí ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, kì í ṣe bí àwọn baba yín ti jẹ manna, tí wọ́n sì kú, ẹni tí ó bá jẹ́ oúnjẹ yìí yóò yè láéláé.”
John 6:58 in English
John 6:58 · Berean Standard Bible
This is the bread that came down from heaven. Unlike your fathers, who ate the manna and died, the one who eats this bread will live forever.”
Context
56Ẹni tí ó bá jẹ ara mi, tí ó bá sì mu ẹ̀jẹ̀ mi, ó ń gbé inú mi, èmi sì ń gbé inú rẹ̀. 57Gẹ́gẹ́ bí Baba alààyè ti rán mi, tí èmi sì yè nípa Baba gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó jẹ mí, òun pẹ̀lú yóò yè nípa mi. 58Èyí sì ni oúnjẹ náà tí ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, kì í ṣe bí àwọn baba yín ti jẹ manna, tí wọ́n sì kú, ẹni tí ó bá jẹ́ oúnjẹ yìí yóò yè láéláé.” 59Nǹkan wọ̀nyí ni ó sọ nínú Sinagọgu, bí ó ti ń kọ́ni ní Kapernaumu. 60Nítorí náà nígbà tí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́ èyí, wọ́n wí pé, “Ọ̀rọ̀ tí ó le ni èyí; ta ní lè gbọ́ ọ?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.