Native Bible

John 6:51 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi ni oúnjẹ ìyè náà tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, bí ẹnikẹ́ni bá jẹ nínú oúnjẹ yìí, yóò yè títí láéláé, oúnjẹ náà tí èmi ó sì fi fún ni fún ìyè aráyé ni ara mi.”

John 6:51 in English

John 6:51 · Berean Standard Bible

I am the living bread that came down from heaven. If anyone eats of this bread, he will live forever. And this bread, which I will give for the life of the world, is My flesh.”

Context

49Àwọn baba yín jẹ manna ní aginjù, wọ́n sì kú. 50Èyí ni oúnjẹ tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, kí ènìyàn lè máa jẹ nínú rẹ̀ kí ó má sì kú. 51Èmi ni oúnjẹ ìyè náà tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, bí ẹnikẹ́ni bá jẹ nínú oúnjẹ yìí, yóò yè títí láéláé, oúnjẹ náà tí èmi ó sì fi fún ni fún ìyè aráyé ni ara mi.” 52Nítorí náà ni àwọn Júù ṣe ń bá ara wọn jiyàn, pé, “Ọkùnrin yìí yóò ti ṣe lè fi ara rẹ̀ fún wa láti jẹ?” 53Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí kò ṣe pé ẹ̀yin bá jẹ ara Ọmọ Ènìyàn, kí ẹ sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ̀yin kò ní ìyè nínú yin.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.