Johanu 6:38
John 6:38 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí èmi sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, kì í ṣe láti máa ṣe ìfẹ́ ti èmi fúnra mi, bí kò ṣe ìfẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.
John 6:38 in English
John 6:38 · Berean Standard Bible
For I have come down from heaven, not to do My own will, but to do the will of Him who sent Me.
Context
36Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, Ẹ̀yin ti rí mi, ẹ kò sì gbàgbọ́. 37Gbogbo èyí tí Baba fi fún mi, yóò tọ̀ mí wá; ẹni tí ó bá sì tọ̀ mí wá, èmi kì yóò tà á nù, bí ó tí wù kó rí. 38Nítorí èmi sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, kì í ṣe láti máa ṣe ìfẹ́ ti èmi fúnra mi, bí kò ṣe ìfẹ́ ti ẹni tí ó rán mi. 39Èyí sì ni ìfẹ́ Baba tí ó rán mi pé ohun gbogbo tí o fi fún mi, kí èmi má ṣe sọ ọ̀kan nù nínú wọn, ṣùgbọ́n kí èmi lè jí wọn dìde níkẹyìn ọjọ́. 40Èyí sì ni ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi, pé ẹnikẹ́ni tí ó bá wo ọmọ, tí ó bá sì gbà á gbọ́, kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun, Èmi ó sì jí i dìde níkẹyìn ọjọ́.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.