Native Bible

John 6:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí wọ́n sì rí i ní apá kejì Òkun, wọ́n wí fún un pé, “Rabbi, nígbà wo ni ìwọ wá síyìn-ín yìí?”

John 6:25 in English

John 6:25 · Berean Standard Bible

When they found Him on the other side of the sea, they asked Him, “Rabbi, when did You get here?”

Context

23Ṣùgbọ́n àwọn ọkọ̀ ojú omi mìíràn ti Tiberia wá, létí ibi tí wọn gbé jẹ àkàrà, lẹ́yìn ìgbà tí Olúwa ti dúpẹ́. 24Nítorí náà nígbà tí àwọn ènìyàn rí i pé Jesu tàbí ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kò sí níbẹ̀, àwọn pẹ̀lú wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Kapernaumu, wọ́n ń wá Jesu. 25Nígbà tí wọ́n sì rí i ní apá kejì Òkun, wọ́n wí fún un pé, “Rabbi, nígbà wo ni ìwọ wá síyìn-ín yìí?” 26Jesu dá wọn lóhùn ó sì wí pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín. Ẹ̀yin ń wá mi, kì í ṣe nítorí tí ẹ̀yin rí iṣẹ́ àmì, ṣùgbọ́n nítorí ẹ̀yin jẹ àjẹyó ìṣù àkàrà. 27Ẹ má ṣe ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tí ń ṣègbé, ṣùgbọ́n fún oúnjẹ tí ó wà títí di ayé àìnípẹ̀kun, èyí tí Ọmọ Ènìyàn yóò fi fún yín. Nítorí pé òun ni, àní Ọlọ́run Baba ti fi èdìdì dì í.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.