Native Bible

John 6:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kó wọn jọ wọ́n sì fi àjẹkù ìṣù àkàrà barle márùn-ún náà kún agbọ̀n méjìlá, èyí tí àwọn tí ó jẹun jẹ kù.

John 6:13 in English

John 6:13 · Berean Standard Bible

So they collected them and filled twelve baskets with the pieces of the five barley loaves left over by those who had eaten.

Context

11Jesu sì mú ìṣù àkàrà náà. Nígbà tí ó sì ti dúpẹ́, ó pín wọn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì pín wọn fún àwọn tí ó jókòó; bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sì ni ẹja ní ìwọ̀n bí wọ́n ti ń fẹ́. 12Nígbà tí wọ́n sì yó, ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ kó àjẹkù tí ó kù jọ, kí ohunkóhun má ṣe ṣòfò.” 13Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kó wọn jọ wọ́n sì fi àjẹkù ìṣù àkàrà barle márùn-ún náà kún agbọ̀n méjìlá, èyí tí àwọn tí ó jẹun jẹ kù. 14Nítorí náà nígbà tí àwọn ọkùnrin náà rí iṣẹ́ àmì tí Jesu ṣe, wọ́n wí pé, “Lóòótọ́ èyí ni wòlíì náà tí ń bọ̀ wá sí ayé.” 15Nígbà tí Jesu sì wòye pé wọ́n ń fẹ́ wá fi agbára mú òun láti lọ fi jẹ ọba, ó tún padà lọ sórí òkè, òun nìkan.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.