Native Bible

John 5:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Kí èyí má ṣe yà yín lẹ́nu; nítorí pé wákàtí ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí ó wà ní ibojì yóò gbọ́ ohun rẹ̀.

John 5:28 in English

John 5:28 · Berean Standard Bible

Do not be amazed at this, for the hour is coming when all who are in their graves will hear His voice

Context

26Nítorí pé gẹ́gẹ́ bí Baba ti ní ìyè nínú ara rẹ̀; gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ó sì fi fún ọmọ láti ní ìyè nínú ara rẹ̀; 27Ó sì fún un ní àṣẹ láti máa ṣe ìdájọ́ pẹ̀lú, nítorí tí òun jẹ́ Ọmọ Ènìyàn. 28“Kí èyí má ṣe yà yín lẹ́nu; nítorí pé wákàtí ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí ó wà ní ibojì yóò gbọ́ ohun rẹ̀. 29Wọn ó sì jáde wá; àwọn tí ó ṣe rere, sí àjíǹde ìyè; àwọn tí ó sì ṣe búburú sí àjíǹde ìdájọ́. 30Èmi kò le ṣe ohun kan fún ara mi, bí mo ti ń gbọ́ ni, mo ń dájọ́, òdodo sì ni ìdájọ́ mi; nítorí èmi kò wá ìfẹ́ ti èmi fúnra mi, bí kò ṣe ìfẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.