Johanu 3:31
John 3:31 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ẹni tí ó ti òkè wá ju gbogbo ènìyàn lọ; ẹni tí ó ti ayé wá ti ayé ni, a sì máa sọ ohun ti ayé. Ẹni tí ó ti ọ̀run wá ju gbogbo ènìyàn lọ.
John 3:31 in English
John 3:31 · Berean Standard Bible
The One who comes from above is above all. The one who is from the earth belongs to the earth and speaks as one from the earth. The One who comes from heaven is above all.*
Context
29Ẹni tí ó bá ni ìyàwó ni ọkọ ìyàwó; ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó tí ó dúró tí ó sì ń gbóhùn rẹ̀, ó ń yọ̀ gidigidi nítorí ohùn ọkọ ìyàwó; nítorí náà ayọ̀ mi yí di kíkún. 30Òun kò lè ṣàì máa pọ̀ sí i, ṣùgbọ́n èmi kò lè ṣàìmá rẹlẹ̀. 31“Ẹni tí ó ti òkè wá ju gbogbo ènìyàn lọ; ẹni tí ó ti ayé wá ti ayé ni, a sì máa sọ ohun ti ayé. Ẹni tí ó ti ọ̀run wá ju gbogbo ènìyàn lọ. 32Ohun tí ó ti rí tí ó sì ti gbọ́ èyí náà sì ni òun ń jẹ́rìí rẹ̀; kò sì sí ẹni tí ó gba ẹ̀rí rẹ̀. 33Ẹni tí ó gba ẹ̀rí rẹ̀ fi èdìdì dì í pé, olóòtítọ́ ni Ọlọ́run.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.