Native Bible

John 3:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí mo bá sọ ohun ti ayé yìí fún yín, tí ẹ̀yin kò sì gbàgbọ́, ẹ̀yin ó ti ṣe gbàgbọ́ bí mo bá sọ ohun ti ọ̀run fún yín?

John 3:12 in English

John 3:12 · Berean Standard Bible

If I have told you about earthly things and you do not believe, how will you believe if I tell you about heavenly things?

Context

10Jesu dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ṣé olùkọ́ni ní Israẹli ni ìwọ ń ṣe, o kò sì mọ nǹkan wọ̀nyí? 11Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Àwa ń sọ èyí tí àwa mọ̀, a sì ń jẹ́rìí èyí tí àwa ti rí; ẹ̀yin kò sì gba ẹ̀rí wa. 12Bí mo bá sọ ohun ti ayé yìí fún yín, tí ẹ̀yin kò sì gbàgbọ́, ẹ̀yin ó ti ṣe gbàgbọ́ bí mo bá sọ ohun ti ọ̀run fún yín? 13Kò sì ṣí ẹni tí ó gòkè re ọ̀run bí kò ṣe ẹni tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, Ọmọ Ènìyàn tí ń bẹ ní ọ̀run. 14Bí Mose sì ti gbé ejò sókè ní aginjù, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni a kò le ṣe aláìgbé Ọmọ Ènìyàn sókè pẹ̀lú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.