Native Bible

John 21:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Peteru sì yípadà, ó rí ọmọ-ẹ̀yìn náà, ẹni tí Jesu fẹ́ràn, ń bọ̀ lẹ́yìn; ẹni tí ó gbara le súnmọ́ àyà rẹ̀ nígbà oúnjẹ alẹ́ tí ó sì wí fún un pé, “Olúwa, ta ni ẹni tí yóò fi ọ́ hàn?”

John 21:20 in English

John 21:20 · Berean Standard Bible

Peter turned and saw the disciple whom Jesus loved following them. He was the one who had leaned back against Jesus * at the supper to ask, “Lord, who is going to betray You?”

Context

18Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, nígbà tí ìwọ wà ní ọ̀dọ́mọdé, ìwọ a máa di ara rẹ ní àmùrè, ìwọ a sì máa rìn lọ sí ibi tí ìwọ bá fẹ́, ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá di arúgbó, ìwọ yóò na ọwọ́ rẹ jáde, ẹlòmíràn yóò sì dì ọ́ ní àmùrè, yóò mú ọ lọ sí ibi tí ìwọ kò fẹ́.” 19Jesu wí èyí, ó fi ń ṣe àpẹẹrẹ irú ikú tí yóò fi yin Ọlọ́run lógo. Lẹ́yìn ìgbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn.” 20Peteru sì yípadà, ó rí ọmọ-ẹ̀yìn náà, ẹni tí Jesu fẹ́ràn, ń bọ̀ lẹ́yìn; ẹni tí ó gbara le súnmọ́ àyà rẹ̀ nígbà oúnjẹ alẹ́ tí ó sì wí fún un pé, “Olúwa, ta ni ẹni tí yóò fi ọ́ hàn?” 21Nígbà tí Peteru rí i, ó wí fún Jesu pé, “Olúwa, Eléyìí ha ń kọ́?” 22Jesu wí fún un pé, “Bí èmi bá fẹ́ kí ó dúró títí èmi ó fi dé, kín ni èyí jẹ́ sí ọ? Ìwọ máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.