Native Bible

John 21:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ wá jẹun òwúrọ̀.” Kò sì sí ẹnìkan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tí ó jẹ́ bí i pé, “Ta ni ìwọ ṣe?” Nítorí tí wọ́n mọ̀ pé Olúwa ni.

John 21:12 in English

John 21:12 · Berean Standard Bible

“Come, have breakfast,” Jesus said to them. None of the disciples dared to ask Him, “Who are You?” They knew it was the Lord.

Context

10Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ mú nínú ẹja tí ẹ pa nísinsin yìí wá.” 11Nítorí náà, Simoni Peteru gòkè, ó sì fa àwọ̀n náà wálẹ̀, ó kún fún ẹja ńlá, ó jẹ́ mẹ́tàléláàádọ́jọ (153) bí wọ́n sì ti pọ̀ tó náà, àwọ̀n náà kò ya. 12Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ wá jẹun òwúrọ̀.” Kò sì sí ẹnìkan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tí ó jẹ́ bí i pé, “Ta ni ìwọ ṣe?” Nítorí tí wọ́n mọ̀ pé Olúwa ni. 13Jesu wá, ó sì mú àkàrà, ó sì fi fún wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹja. 14Èyí ni ìgbà kẹta nísinsin yìí tí Jesu farahan àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí ó jíǹde kúrò nínú òkú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.