Johanu 20:13
John 20:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, èéṣe tí ìwọ fi ń sọkún?” Ó sì wí fún wọn pé, “Nítorí tí wọ́n ti gbé Olúwa mi, èmi kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí.”
John 20:13 in English
John 20:13 · Berean Standard Bible
“Woman, why are you weeping?” they asked. “Because they have taken my Lord away,” she said, “and I do not know where they have put Him.”
Context
11Ṣùgbọ́n Maria dúró létí ibojì lóde, ó ń sọkún: bí ó ti ń sọkún, bẹ́ẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀, ó sì wo inú ibojì. 12Ó sì kíyèsi àwọn angẹli méjì aláṣọ funfun, wọ́n jókòó, ọ̀kan níhà orí àti ọ̀kan níhà ẹsẹ̀, níbi tí òkú Jesu gbé ti sùn sí. 13Wọ́n sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, èéṣe tí ìwọ fi ń sọkún?”
Ó sì wí fún wọn pé, “Nítorí tí wọ́n ti gbé Olúwa mi, èmi kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí.” 14Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó yípadà, ó sì rí Jesu dúró, kò sì mọ̀ pé Jesu ni. 15Jesu wí fún un pé, “Obìnrin yìí, èéṣe tí ìwọ fi ń sọkún? Ta ni ìwọ ń wá?”
Òun ṣe bí olùṣọ́gbà ní í ṣe, ó wí fún un pé, “Alàgbà, bí ìwọ bá ti gbé e kúrò níhìn-ín yìí, sọ ibi tí ìwọ tẹ́ ẹ sí fún mi, èmi yóò sì gbé e kúrò.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.