Johanu 19:40
John 19:40 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé òkú Jesu, wọ́n sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ dì í pẹ̀lú tùràrí, gẹ́gẹ́ bí ìṣe àwọn Júù ti rí ní ìsìnkú wọn.
John 19:40 in English
John 19:40 · Berean Standard Bible
So they took the body of Jesus and wrapped it in linen cloths with the spices, according to the Jewish burial custom.
Context
38Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ní Josẹfu ará Arimatea, ẹni tí ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jesu, ní ìkọ̀kọ̀, nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù, o bẹ Pilatu kí òun lè gbé òkú Jesu kúrò, Pilatu sì fún un ní àṣẹ. Nígbà náà ni ó wá, ó sì gbé òkú Jesu lọ. 39Nikodemu pẹ̀lú sì wá, ẹni tí ó tọ Jesu wá lóru lákọ̀ọ́kọ́, ó sì mú àdàpọ̀ òjìá àti aloe wá, ó tó ìwọ̀n ọgọ́rùn-ún lita. 40Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé òkú Jesu, wọ́n sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ dì í pẹ̀lú tùràrí, gẹ́gẹ́ bí ìṣe àwọn Júù ti rí ní ìsìnkú wọn. 41Àgbàlá kan sì wà níbi tí a gbé kàn án mọ́ àgbélébùú; ibojì tuntun kan sì wà nínú àgbàlá náà, nínú èyí tí a kò tí ì tẹ́ ẹnìkan sí rí. 42Ǹjẹ́ níbẹ̀ ni wọ́n sì tẹ́ Jesu sí, nítorí ìpalẹ̀mọ́ àwọn Júù; àti nítorí ibojì náà wà nítòsí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.