Johanu 19:29
John 19:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ohun èlò kan tí ó kún fún ọtí kíkan wà níbẹ̀, wọ́n tẹ kànìnkànìn tí ó kún fún ọtí kíkan bọ inú rẹ̀, wọ́n sì fi lé orí igi hísópù, wọ́n sì nà án sí i lẹ́nu.
John 19:29 in English
John 19:29 · Berean Standard Bible
A jar of sour wine * was sitting there. So they soaked a sponge in the wine, put it on a stalk of hyssop, and lifted it to His mouth.*
Context
27Lẹ́yìn náà ni ó sì wí fún ọmọ-ẹ̀yìn náà pé, “Wo ìyá rẹ!” Láti wákàtí náà lọ ni ọmọ-ẹ̀yìn náà sì ti mú un lọ sí ilé ara rẹ̀. 28Lẹ́yìn èyí, bí Jesu ti mọ̀ pé, a ti parí ohun gbogbo tán, kí ìwé mímọ́ bà á lè ṣẹ, ó wí pé, “Òrùngbẹ ń gbẹ mí.” 29Ohun èlò kan tí ó kún fún ọtí kíkan wà níbẹ̀, wọ́n tẹ kànìnkànìn tí ó kún fún ọtí kíkan bọ inú rẹ̀, wọ́n sì fi lé orí igi hísópù, wọ́n sì nà án sí i lẹ́nu. 30Nígbà tí Jesu sì ti gba ọtí kíkan náà, ó wí pé, “Ó parí!” Ó sì tẹ orí rẹ̀ ba, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀. 31Nítorí ó jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́, kí òkú wọn má ba à wà lórí àgbélébùú ní ọjọ́ ìsinmi (nítorí ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ ìsinmi náà), nítorí náà, àwọn Júù bẹ Pilatu pé kí a ṣẹ́ egungun itan wọn, kí a sì gbé wọn kúrò.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.