Johanu 19:10
John 19:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà, Pilatu wí fún un pé, “Èmi ni ìwọ kò fọhùn sí? Ìwọ kò mọ̀ pé, èmi ní agbára láti dá ọ sílẹ̀, èmi sì ní agbára láti kàn ọ́ mọ́ àgbélébùú?”
John 19:10 in English
John 19:10 · Berean Standard Bible
So Pilate said to Him, “Do You refuse to speak to me? Do You not know that I have authority to release You and authority to crucify You?”
Context
8Nítorí náà nígbà tí Pilatu gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀rù túbọ̀ bà á. 9Ó sì tún wọ inú gbọ̀ngàn ìdájọ́ lọ, ó sì wí fún Jesu pé, “Níbo ni ìwọ ti wá?” Ṣùgbọ́n Jesu kò dá a lóhùn. 10Nítorí náà, Pilatu wí fún un pé, “Èmi ni ìwọ kò fọhùn sí? Ìwọ kò mọ̀ pé, èmi ní agbára láti dá ọ sílẹ̀, èmi sì ní agbára láti kàn ọ́ mọ́ àgbélébùú?” 11Jesu dá a lóhùn pé, “Ìwọ kì bá tí ní agbára kan lórí mi, bí kò ṣe pé a fi í fún ọ láti òkè wá, nítorí náà ẹni tí ó fi mí lé ọ lọ́wọ́ ni ó ní ẹ̀ṣẹ̀ pọ̀jù.” 12Nítorí èyí, Pilatu ń wá ọ̀nà láti dá a sílẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn Júù kígbe, wí pé, “Bí ìwọ bá dá ọkùnrin yìí sílẹ̀, ìwọ kì í ṣe ọ̀rẹ́ Kesari: ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ara rẹ̀ ní ọba, ó sọ̀rọ̀-òdì sí Kesari.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.